Who cast that first fateful tomato that started the La Tomatina revolution? The reality is no one knows. Maybe it was an anti-Franco rebellion, or a carnival that got out of hand. According to the most popular version of the story, during the 1945 festival of Los Gigantes (a giant paper mâché puppet parade), locals were looking to stage a brawl to get some attention. They happened upon a vegetable cart nearby and started hurling ripe tomatoes. Innocent onlookers got involved until the scene escalated into a massive melee of flying fruit. The instigators had to repay the tomato vendors, but that didn't stop the recurrence of more tomato fights—and the birth of a new tradition.
Fearful of an unruly escalation, authorities enacted, relaxed, and then reinstated a series of bans in the 1950s. In 1951, locals who defied the law were imprisoned until public outcry called for their release. The most famous effrontery to the tomato bans happened in 1957 when proponents held a mock tomato funeral complete with a coffin and procession. After 1957, the local government decided to roll with the punches, set a few rules in place, and embraced the wacky tradition.
Though the tomatoes take center stage, a week of festivities lead up to the final showdown. It's a celebration of Buñol's patron saints, the Virgin Mary and St. Louis Bertrand, with street parades, music, and fireworks in joyous Spanish fashion. To build up your strength for the impending brawl, an epic paella is served on the eve of the battle, showcasing an iconic Valencian dish of rice, seafood, saffron, and olive oil.
Today, this unfettered festival has some measure of order. Organizers have gone so far as to cultivate a special variety of unpalatable tomatoes just for the annual event. Festivities kick off around 10 a.m. when participants race to grab a ham fixed atop a greasy pole. Onlookers hose the scramblers with water while singing and dancing in the streets. When the church bell strikes noon, trucks packed with tomatoes roll into town, while chants of "To-ma-te, to-ma-te!" reach a crescendo.
Then, with the firing of a water cannon, the main event begins. That's the green light for crushing and launching tomatoes in all-out attacks against fellow participants. Long distance tomato lobbers, point-blank assassins, and medium range hook shots. Whatever your technique, by the time it's over, you will look (and feel) quite different. Nearly an hour later, tomato-soaked bombers are left to play in a sea of squishy street salsa with little left resembling a tomato to be found. A second cannon shot signals the end of the battle. | Tani o kọkọ ju tomati akọkọ naa ti da iṣọtẹ La Tomatina silẹ? Otitọ ibẹ ni wipe ko si ẹni ti o mọ. Boya iṣọtẹ alodi si ijọba Faranse tabi ayẹyẹ idaraya ti o kọja ààlà ni. Gẹge bii ẹya itan ti o wọpọ julọ, ni igba ayẹyẹ ti Los Gigantisi (tito awọn ère nla ti a fi pépà ṣe kọja) ti ọdun 1945, awọn ara adugbo nfẹ ṣeto ija kan lati pe awọn eniyan sọdọ wọn. Ni wọn ba kan ọmọlanke ewebẹ kan ni arọwọto ti wọn si bẹrẹ si ni sọ awọn tomati ti o ti pọn. Awọn oluworan ti ko mọ nkankan ba da sii titi ti iran naa fi di ija-igboro nla ti eso to nfo. Awọn ti o fàá ni lati san owó fun awọn ti o nta tomati naa, ṣugbọn eyi ko da wiwaye awọn ija tomati duro—ati ìbí aṣa atọwodọ titun kan. Awọn alaṣẹ, ni ibẹru iwa ti wọn ko ni le kapa, ṣe ofin, wọn tun rẹ ọwọ ofin naa silẹ, nigba ti o ya wọn tun mupada sipo awọn ofin ti o dèé lẹsẹsẹ ni awọn ọdun 1950. Ni ọdun 1951, awọn ara adugbo ti o tapa si ofin ni wọn timọle titi ti igbe awọn ara ilu fi pè fun itusilẹ wọn. Itapa si fifi ofin de tomati ti o lokiki julọ ṣẹlẹ ni ọdun 1957 nigbati awọn olufilọlẹ ṣe isinku ẹgan tomati kan pẹlu posi ati iwọde. Lẹyin ọdun 1957, ijọba ibilẹ pinnu lati ba igba mu, wọn fi awọn ofin kan lelẹ, ti wọn si faramọ aṣa atọwọdọwọ adẹrin pani naa. Bi o tilẹ jẹ wipe tomati ni o gbajumọ julọ, awọn ayẹyẹ ọlọsẹ kan maa nwaye ṣaaju asekagba yi. O jẹ ajọyọ ti awọn eniyan mimọ alatilẹyin Buñol, Wundia Maria ati St Louis Bertrand, pẹlu iwọde ni opopona, orin, ati fifi ina-mèremère dara pẹlu ayọ ni aṣa Spaniṣi. Lati mu agbara rẹ le fun ija igboro to nbọ, ounjẹ atijọ ti spaniṣi ni wọn maa njẹ ni alẹ ti o ṣaaju ija naa, eyiti o nfi irẹsi ti o gbajumọ ti Falenṣia, ohun jijẹ lati inu okun, ìtànná safurọnu, ati ororo olifi han. Loni, ayẹyẹ alaini idiwọ yii ti ni awọn odiwọn ètò. Awọn oluṣeto ti tẹsiwaju de bii wipe wọn gbin iru awọn tomati kan ti ko ṣe e jẹ fun iṣẹlẹ ọdọọdun naa. Ajọdun maa nbẹre ni bi aago mẹwa owurọ (10 a.m) nigbati awọn olukopa ba sare lati lọ gba ẹran ẹlẹda ti a ti yan ti o wa loke opo ti ti fi girisi yi mu. Awọn oluworan yoo maa tu omi si awọn ti o nwọ kiri naa lara ni bi wọn ṣe nkọrin ti wọn si njo ni awọn opopona. Ni igbati ti aago ṣọọṣi ba dun ni ọsan gan-gan, awọn ọkọ ti a ti di tomati si yoo wọlu, nigbati ariwo "Tomati, tomato!" yoo ta. Nigbanaa, pẹlu yinyin ibọn olomi, iṣẹlẹ gan-gan yoo bẹrẹ. Eyi ni imọlẹ atọka fun rírún ati jíju awọn tomati ni gbogbo ọna lati dojukọ awọn olukopa miiran. Awọn ti o le ju tomati lọ jinna rere, awọn asun mọni pani, ati awọn jiju ti ko jinna ju. Eyikeyi ti o jẹ ọna tirẹ, ni igba ti o ba pari, iwọ yoo da (ti iwọ yoo si ni imọlara) yatọ. Ni bii wakati lẹyin naa, awọn alado adugbamu ti tomati ti rin ni a o fi silẹ lati ṣere ninu okun opopona pẹlu tomati diẹ to sẹku lati wá rí. Ibọn yinyin elẹẹkeji yoo fi aami opin ija naa han. |