Who cast that first fateful tomato that started the La Tomatina revolution? The reality is no one knows. Maybe it was an anti-Franco rebellion, or a carnival that got out of hand. According to the most popular version of the story, during the 1945 festival of Los Gigantes (a giant paper mâché puppet parade), locals were looking to stage a brawl to get some attention. They happened upon a vegetable cart nearby and started hurling ripe tomatoes. Innocent onlookers got involved until the scene escalated into a massive melee of flying fruit. The instigators had to repay the tomato vendors, but that didn't stop the recurrence of more tomato fights—and the birth of a new tradition.
Fearful of an unruly escalation, authorities enacted, relaxed, and then reinstated a series of bans in the 1950s. In 1951, locals who defied the law were imprisoned until public outcry called for their release. The most famous effrontery to the tomato bans happened in 1957 when proponents held a mock tomato funeral complete with a coffin and procession. After 1957, the local government decided to roll with the punches, set a few rules in place, and embraced the wacky tradition.
Though the tomatoes take center stage, a week of festivities lead up to the final showdown. It's a celebration of Buñol's patron saints, the Virgin Mary and St. Louis Bertrand, with street parades, music, and fireworks in joyous Spanish fashion. To build up your strength for the impending brawl, an epic paella is served on the eve of the battle, showcasing an iconic Valencian dish of rice, seafood, saffron, and olive oil.
Today, this unfettered festival has some measure of order. Organizers have gone so far as to cultivate a special variety of unpalatable tomatoes just for the annual event. Festivities kick off around 10 a.m. when participants race to grab a ham fixed atop a greasy pole. Onlookers hose the scramblers with water while singing and dancing in the streets. When the church bell strikes noon, trucks packed with tomatoes roll into town, while chants of "To-ma-te, to-ma-te!" reach a crescendo.
Then, with the firing of a water cannon, the main event begins. That's the green light for crushing and launching tomatoes in all-out attacks against fellow participants. Long distance tomato lobbers, point-blank assassins, and medium range hook shots. Whatever your technique, by the time it's over, you will look (and feel) quite different. Nearly an hour later, tomato-soaked bombers are left to play in a sea of squishy street salsa with little left resembling a tomato to be found. A second cannon shot signals the end of the battle. | Tani ó kọ́kọ́ ju tòmátì náà èyí tí ó bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ ti La Tomatina? Òtítọ́ rẹ nipé kòsí ẹni tí ó mọ̀. Bóyá ìṣọ̀tẹ̀ aṣòdìsí Franko ni, tàbí àjọyọ̀ ìwọ́de ijó àti ilù tí ó ṣèṣì bọ́ sódì. Lára èyí tí ó wọ́pọ̀ nínu ìtàn náà, lákókò ajọ̀dún 1945 ti Los Gigante ( ìṣafihàn òmìrán àfi pépà ṣe), àwọn ìbílẹ̀ ń fa asọ̀ láti lè jẹ́kí wọ́n fiyèsí wọn. Wọ́n gúnlè kèké tí ńkó ewébẹ̀ ní ìtòsí tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síní ju tòmátì pípọ́n. Àwọn olùwòran kópa nínu rẹ̀ tí ìwà yíi fi gbìnàyá sí jíju ohun èso ńlá. Àwọn tí ó ṣokunfà èyí nílò láti san owó ìdápadà fún olùta tòmátì, ṣùgbọ́n èyí kò dáwọ́ ìjù padà àwọn ìjà tòmátì dúró—àti ìṣẹ̀dá àṣà titun. Nítorí ìbẹrù ìrusókè tí akòle ṣàkóso, àwọn aláṣẹ pá láṣẹ, dẹwọ́, wọ́n sì tún ṣàfílélẹ̀ oríṣi ìfilọ̀ ìtagbangba ní àwọn ọdún 1950. Ni 1951, àwọn ìbílẹ̀ tí ó tàpá sófin yìí ní a tì mọ́lé títí tí àwọn ará ìlu kígbe síta fún ìdásílẹ̀ wọn. Ìṣáfojúdi tí ó lókìkí jùlọ sí ìfilọ̀ ìtagbangba ṣẹlẹ̀ ní 1957 nígbà tí àwọn olúdásílẹ̀ ṣe ìṣẹfẹ̀ ìtòkú tòmátì pẹ̀lú odindi pósí àti ìwọ́de ọ̀pọ̀ ènìyàn. Lẹ́hìn 1957, ìjọba ìbílẹ̀ dẹwọ́, wọ́n ṣe òfin titun, wọ́n sì faramọ́ àṣà aṣiwerè yíì. Bí-ó-tilẹ̀-jẹ́ wí pé tòmátì gba òde kan, ọ̀sẹ̀ kan ajòdún ṣòkunfà ọjọ́ ìkẹhìn ìfigagbága. Ó jẹ́ àjọyọ̀ ẹni mímọ́ aláàbò Buñol, Màríà Wúndíá àti Ẹni mímọ́ Louis Bertrand, pẹ̀lú ìwọ́de òpónà, orin, àti ayẹyẹ oríṣi iná jíjó ní ìlanà àjọyọ̀ àṣà ará Sípáìn. Láti ṣè’gbáradì okun rẹ fún asọ̀ tí ń bọ̀, a ńṣe ìpesè oúnjẹ àrà ọ̀tọ̀ onírẹsì ní alẹ́ ṣáájú ọjọ́ ogun, èyí tí ń ṣàfihàn ìrí Àkójọpọ̀ àwopọ̀kọ́ ìrẹsì, oúnjẹ odò, òdòdó àrà ọ̀tọ̀, àti òróró ólífì. Lónì, àjọ̀dún àìnídinwọ̀n yíi ní gbèndéke ètò. Àwọn olùgbékalẹ̀ ti rìn jìnnà ní gbíngbin àwọn àrà ọ̀tọ̀ tòmátì tí kò dùn lẹ́nu fún ètò ọdọdún yìí nìkan. Àjọ̀dún bẹ̀rẹ̀ ní bii agogo mẹ́wà òwúrọ̀, nígbà tí àwọn olùkópa sáré láti mú ẹran tí a somọ́ orí òpó yíyọ̀. Àwọn olùwóran tú omi sí ara àwọn olùjìjàdù nígbà tí wọ́n ń kọrin pẹ̀lú ijó ní òpópó. Nígbà tí ago ilé ìjọsìn lù lọ́sàn, àwọn ọkọ̀ tí ó kó tòmátì wọ̀’lú, nígbà tí ariwo "Tò-má-tì, tò-má-tì" dé góńgó. Nígbà náà, pẹ̀lú ìfomi s’ọ̀kò, ayẹyẹ gan an bẹ̀rẹ̀. Èyí ni ààmì fún ìfúnpa àti jíju tòmátì lòdì sí olùkópa mííràn. Olùjù tòmátì lọ́nà jínjín réré, apànìa ojúkojú, àti jíju àìjìnà. Èyíkéyì ọ̀nà ìṣàmúlò rẹ, nígbà tí àkókò yóò parí, wá (nímọ̀lárà) ti yatọ̀. Léhìn bii wákàtí kan, àwọn olùju àdó olóró tí ó rin pẹ̀lú tòmátì laófi sílẹ̀ láti ṣeré nínu òpópó èrojà tòmátì tí ó rọ̀ dẹ̀mùdẹ̀mù pẹ̀lú ohun kéréje tí ó jọ tòmátì tí a lèrí. Àgbá ìkejì tí a yìn ṣàfihàn òpin ogun. |